Ninu irin ajomi , Beeni mo n korin

Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin
Mo n toka si kalfari, N’ibi eje na
Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide
Jesu lo nto mi lo, isegun daju

Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.

 

Ninu ise isin mi, b’okunkun basu
Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole
Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada
Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi.

 

Bi mo tile bo sinu afonifoji
Imole itoni Re, Yio Mole simi
Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke
Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo

 

Nigbati iji aye yi ba yi lu mi
Mo ni abo t’o daju, labe apa re
Y’o ma f’owo re to mi titi de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f’e to.

4 comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.